Ojo Konkanlelogun Osu Kewa Odun  2014 E kaabo si ALAROYE.... iwe iroyin ti n soju omo Yoruba nibi gbogbo
 
 
 
::Alaroye - iwe iroyin ti n soju omo yoruba nibi gbogbo::
 
Kwara 2015: Bii ogorun-un meji eeyan lo fee dije fun ipo merinlelogbon legbe PDP Kwara
Pelu bi eto idibo gbogbo-gbo odun to n bo se n sunmo etile, o kere tan eeyan bii ogorun-un meji din ni mokandinlogbon, 171, lo ti fife han lati dupo merinlelogbon to wa nipinle Kwara labe egbe oselu PDP.
Idajo ibo 2011 di wahala l'Osun, APC ati PDP tun soko oro sira won
Ile-ejo ko-te-mi-lorun to wa niluu Akure, ti so pe alaga ajo eleto idibo nipinle Osun, Ambasado Rufus Akeju, ko letoo lati dari eto idibo apapo sile igbimo asofin ipinle Osun, ile igbimo asofin apapo ati ile igbimo asofin agba to waye lodun 2011.
 
Iru agbara wo ni Ooni ni, iru agbara wo si ni Alaafin ni?
Olorun Olodumare, fun wa ni emi agboye nile Yoruba, ki a gbo oro ara wa ye, ki oro wa ma se daru loju ara wa. Awon miiran ko ni agboye oro ti mo n so yii to, loju tiwon, bii igba ti mo n gbiyanju lati fi Okunade Sijuwade se olori Lamidi Adeyemi ni.
 
Wahala de, Eagles ha poo
Egbe agbaboolu Super Eagles ile Naijiria ti ha bayii leyin ifesewonse kuolifaya to waye laarin awon ati egbe agbaboolu ile Sudan, iyen Falcons, nigba tawon yen je ami-ayo kan mo won lara lojo Abameta, Satide, to koja, eyi to ti di wahala nla bayii.
Sugbon Falcons derin-in peeke Naijiria
Egbe agbaboolu obinrin ile wa, Super Falcons, ti derin peeke awon ololufe boolu lorile-ede yii latari bi won se lu orile-ede Cote d’Ivoire ni ami-ayo merin si meji nibi idije awon obinrin ile Afrika todun yii to n lo lowo lorile-ede Namibia.
 
 
 
IROYIN ORISIRISI
Baba arugbo ku sori ale l'Odogbolu

Adura tawon okunrin kan maa n se ni pe ki Olorun ma je kawon gba ibi tawon gba waye lo sorun,

Eye to deeyan l’Oshodi ti ku o

Ileese olopaa ipinle Eko ti kede pe eye to deeyan lori biriiji elese to wa l’Osodi lojo Eti,

Mo sewon ti mo le se l’Ekiti, e gbadura funjoba to n bo—Fayemi

Gomina ipinle Ekiti ti yoo fipo sile lola, Dokita Kayode Fayemi,

Lose yii ni won yoo bura fun Fayose

Gbogbo eto lo ti to bayii lati sebura iwole fun gomina tuntun nipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose,

Won ti tun bere o: Awon ti won fee ta ile Yoruba fun Jonathan ree

Olusegun Obasanjo binu. Baba naa fibinu soro sawon ti won n be e ninu egbe PDP,

L'Ondo, Nwanyanwu bu sekun lori bi Mimiko se fegbe Labour sile

Iyanu loro ohun je fawon eeyan to wa nibi ipade gbogbogboo ohun,

Nnkan de! Won ba ori oku lowo wolii ni Modakeke

"E gba mi o, e ma je ki won pa mi o, won ti n bo o, e wo ori to n le mi o!"

Awon omo-eyin Gbenga Daniel kan ko ba a lo si PDP

Lati bii osu meloo kan seyin loro naa ti n ja nile pe laipe ni egbe oselu Labour nipinle Ogun


 

                   © 2011 Ile ise Alaroye Powered by Future Global Integrated Resources Ltd.